|
Post by seenesco on Mar 26, 2013 5:10:31 GMT -5
1. Ilé-ifè ni orí’run ayé Ìlú Oòduà baba Yorùbá Èdùmàrè tó dá wa sí’fè Kó máse ba ’fe jé mó wa l’órí K’Olúwa kó maa ràn wá se.
Refrain Ifè Oòyè, E jí gìrì E jí gìrì, k’e gbé Ifè ga Olórí aye ni’fè Oòyè K’á múra láti tè s’íwájú Òràmfè On’ílé iná Oòduà a wèriri jagun Òkànlén’írún irúnmolè E gbé ’fè lé’kĕ ’sòro gbogbo
2. Ilé-ifè b’ojúmó ti mó wá Ìlú àsà on ìlú èsìn Gbogbo Yorùbá e káre ’fè Ká lo w’ohun àdáyébá t’ó jo’jú Ilé Oòduà Ifè l’ó wà Opá Òràn’yàn; Ilé-Ifè ni. ’ Boji Morèmi Ilé-Ifè ni Ará, e káre ’fè Oòdáyé.
Refrain Ifè Oòyè, E jí gìrì E jí gìrì, k’e gbé Ifè ga Olórí aye ni’fè Oòyè K’á múra láti tè s’íwájú Òràmfè On’ílé iná Oòduà a wèriri jagun Òkànlén’írún irúnmolè E gbé ’fè lé’kĕ ’sòro gbogbo
|
|